Yoruba
Permanent URI for this collection
Browse
Browsing Yoruba by Subject "Ohun-ogbin"
Now showing 1 - 1 of 1
Results Per Page
Sort Options
Item Ki wọ́n jẹ́ kí obìnrin kópa lásìkò tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ àti tí wọ́n bá ń dán àwọn àgbàdo tí ó lè fara da ọ̀gbẹlẹ̀ wò(2023-10-02) ST CommunicationsIpa tí ó lápẹẹrẹ ni àwọn obìnrin ń kó nínú pípèsè ohun-ọ̀gbìn àti ìdáàbòò oúnjẹ jíjẹ nínú ilé. Àmọ́ ṣá, ìkópa àwọn obìnrin nínú ìsedánwò àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n pèsè fún ohun-ọ̀gbìn nínú-oko kéré. Nínú ìwádìí yìí, a lo àtòjọ-ìbéèrè tó ní ètò láti gba dátà, wọ́n fún àwọn àgbẹ̀ obìnrin 80 nínú ìṣedánwò àgbàdo tí ó lè fara da ọ̀gbẹlẹ (DT)̀ ní ilẹ̀ Pápá Southern Guinea (SGS) Ajẹmọ́-ohun-ọ̀gbìn ojú ọjọ́ Ẹkùn ti Nigeria. Ìwádìí náà fi hàn pé gbogbbo àwọn àgbẹ̀ obìnrin náà ni wọ́n ti lọ́kọ, bíi 23% wọn ni wọn kò lọ ilé-ìwé rárá, tí ìgbèdéke ọjọ́-orí wọn sì tó ẹni ọdún 43. Ní gbogbo àwọn ìbùdó ni àwọn àgbẹ̀ obìnrin ti gbé ẹ̀yà àgbàdo DT sí ipò tí ó dára jùlọ. Fún ìdí èyí a gbà á níyànjú pé kí àwọn àgbẹ̀ obìnrin máa kópa nínu ṣíṣe ìgbéǹde àti ìdánwo ráńpẹ́ fún àwọn òye tuntun lẹ́nu iṣẹ́ ohun ọ̀gbìn láti rí dájú pé ààbò wà fún oúnjẹ kí wọn ó sì ní ìdàgbàsókè ọlọ́jọ́ pípẹ́ nípasẹ̀ ìpèsè ìrànwọ́ fún iṣẹ́ ohun ọ̀gbìn.