Yoruba
Permanent URI for this collection
Browse
Recent Submissions
Item Ki wọ́n jẹ́ kí obìnrin kópa lásìkò tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ àti tí wọ́n bá ń dán àwọn àgbàdo tí ó lè fara da ọ̀gbẹlẹ̀ wò(2023-10-02) ST CommunicationsIpa tí ó lápẹẹrẹ ni àwọn obìnrin ń kó nínú pípèsè ohun-ọ̀gbìn àti ìdáàbòò oúnjẹ jíjẹ nínú ilé. Àmọ́ ṣá, ìkópa àwọn obìnrin nínú ìsedánwò àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n pèsè fún ohun-ọ̀gbìn nínú-oko kéré. Nínú ìwádìí yìí, a lo àtòjọ-ìbéèrè tó ní ètò láti gba dátà, wọ́n fún àwọn àgbẹ̀ obìnrin 80 nínú ìṣedánwò àgbàdo tí ó lè fara da ọ̀gbẹlẹ (DT)̀ ní ilẹ̀ Pápá Southern Guinea (SGS) Ajẹmọ́-ohun-ọ̀gbìn ojú ọjọ́ Ẹkùn ti Nigeria. Ìwádìí náà fi hàn pé gbogbbo àwọn àgbẹ̀ obìnrin náà ni wọ́n ti lọ́kọ, bíi 23% wọn ni wọn kò lọ ilé-ìwé rárá, tí ìgbèdéke ọjọ́-orí wọn sì tó ẹni ọdún 43. Ní gbogbo àwọn ìbùdó ni àwọn àgbẹ̀ obìnrin ti gbé ẹ̀yà àgbàdo DT sí ipò tí ó dára jùlọ. Fún ìdí èyí a gbà á níyànjú pé kí àwọn àgbẹ̀ obìnrin máa kópa nínu ṣíṣe ìgbéǹde àti ìdánwo ráńpẹ́ fún àwọn òye tuntun lẹ́nu iṣẹ́ ohun ọ̀gbìn láti rí dájú pé ààbò wà fún oúnjẹ kí wọn ó sì ní ìdàgbàsókè ọlọ́jọ́ pípẹ́ nípasẹ̀ ìpèsè ìrànwọ́ fún iṣẹ́ ohun ọ̀gbìn.Item Àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè South Africa tí ó ní HIV àti CD4 tó kéré súmọ́ ewu àtiní jẹjẹrẹ gidi gan-an.(2023-10-02) ST CommunicationsA ṣàfikún ọjọ́-orí 15 sí 24 nínú ìwádìí àpawọ́pọ̀ṣe lórí HIV àti jẹjẹrẹ ní orílẹ̀-èdè South Africa, ẹ̀gbé tó tóbi tí ó jẹ́ àyọrísí ìsopọ̀ láàrin òsùwon àyẹ̀wò ajẹmọ́-HIV láti ilé-iṣẹ́ ibùdó àyẹ̀wò ètò-ìlera àpapọ̀ orílẹ̀-èdè àti ibùdó àpapọ̀ àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ jẹjẹrẹ. A ṣàkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn jẹjẹrẹ tí ó wọ́pọ̀ jùlọ. A wo ìkanra láàrin àwọn jẹjẹrẹ náà àti ẹ̀yà-ìbí, ọdún ìbí, àti iye kuulu-ẹ̀jẹ̀ CD4 pẹ̀lú ìṣàmúlò módẹ́ẹ̀lì Cox àti òṣùwòn alátúntò ásáàdì (aHR).Item Àwọn oníwádìí sọ pé fáírọ́ọ̀sì COVID-19 lè má tètè yírapadà, èyí tó jẹ́ kí ṣíṣe àjẹ́sára yá(2023-10-02) ST CommunicationÀjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ láti ìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀ ní ìparí osù Belu ọdún 2019 ní Wuhan, China. Lílo òye àti ṣiṣe àbójútó ìtànkálẹ̀ ìpilẹ̀-ara fáírọ́òsì náà, àwọn àbùdá agbègbè rẹ̀, àti ìdúróṣin rẹ̀ ṣe pàtàkì fún àti ṣe ìsàkóso ìtànkálẹ̀ àrùn náà àti fún ìdàgbàsókè àjẹsára káríayé tó bo gbogbo àwọn iṣan. Láti ìhà yìí, a ṣe àtúpalẹ̀ ìpìlẹ̀-ara 30,983 SARS-CoV-2 láti àwọn orílé-ède 79 tó wà ní oríṣiríṣi kọ́ńtínẹ́ẹ̀tì mẹ́fà tí a sì gbà láti 24 oṣù Ọpẹ́ ọdún 2019, títí dé 13 osù Èbìbí 2020, ní ìbámu pẹ̀lú àkójọ dátà ti GISAID. Àtúpalẹ̀ wa fi ààyè ìyàtọ̀ 3206 hàn, pẹ̀lú ìṣọ̀kan ìfọnká irúfẹ́ ìyípadà ní oríṣiríṣi agbègbè. Pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, a ti ṣe àkíyèsí ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ìyípadà lóòrẹ̀kóòrè; ìyípadà 169 péré (5.27%) ní ìtànkálẹ̀ ìpìlẹ̀-ara tí ó tóbi jù pẹ̀lú 1%. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọ́n àmúkù mẹ́rìnlá tí kò bára jọ (>10%) ní a ti ṣèdámọ̀ ní àwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ibi ìpìlẹ̀-ara; mẹ́jọ nínú ORF1ab (nínú nsp2, nsp3, àyè awọ, RdRp, ẹ́líkeèsì, ẹksonukílìs àti ẹndoribonukílíìsì), mẹ́ta nínú amúaradàgbà nukilioscásíìdì, àti ọ̀kà nínú purotéènì mẹ́ta:Item Àwọn aráàlú Uganda tó ní àrùn kọ̀kòrò HIV àti ẹ̀jẹ̀ ríru ò rí ìtọ́jú tí ó péye gbà(2023-10-02) ST CommunicationsÀwọn èèyàn tó ń gbé pẹ̀lú HIV (PLHIV) tó sì ń gba ìtọ́jú àìlera antiretroviral ní ewu púpọ̀ tó jẹ mọ́ àrùn ọkàn àti ti ẹ̀jẹ̀ (CVD). Asopọ̀ iṣẹ́ fún ẹ̀jẹ̀ ríru (HTN), èyí tó jẹ́ ewu CVD àkọ́kọ́, sínú àwọn ilé-ìwòsàn HIV tí wọ́n ṣe ìdúró fún ní orílé-èdè Uganda. Iṣẹ́ wa ìṣáájú ṣe àfihàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlààfo tí a lè lò fi sẹ àmúlò ìsopọ̀ ìtọ́jú HTN pẹ̀lu ọgbọ́ń ìtọ́jú HIV lẹ́sẹẹsẹ. Nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí, a wá láti ṣàwárí àwọn ohun ìdènà sí ti àwọn tó wà ní ìdí ìbojúwo ìṣàkóso ìsopọ̀ HTN àti ìtọ́jú sí àwọn ilé ìwòsàn HIV ní Ilà-Oòrùn ilẹ̀ Uganda.